ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 53:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Torí ìyẹn, màá fún un ní ìpín láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀,

      Ó sì máa pín ẹrù ogun pẹ̀lú àwọn alágbára,

      Torí ó tú ẹ̀mí* rẹ̀ jáde, àní títí dé ikú,+

      Wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀;+

      Ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn,+

      Ó sì bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bẹ̀bẹ̀.+

  • Jòhánù 3:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 “Torí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni,+ kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+

  • Éfésù 2:4, 5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Àmọ́ Ọlọ́run, tí àánú rẹ̀ pọ̀,+ nítorí ìfẹ́ ńlá tó ní sí wa,+ 5 sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi, kódà nígbà tí a kú nínú àwọn àṣemáṣe wa,+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ mú kí ẹ rí ìgbàlà.

  • 1 Pétérù 3:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀, Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún kú mọ́ láé,+ ó jẹ́ olódodo tó kú nítorí àwọn aláìṣòdodo,+ kó lè mú yín wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ Wọ́n pa á nínú ẹran ara,+ àmọ́ a sọ ọ́ di ààyè nínú ẹ̀mí.+

  • 1 Jòhánù 4:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Bí ìfẹ́ náà ṣe jẹ́ nìyí, kì í ṣe pé àwa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ kó lè jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù*+ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́