Òwe 11:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Ọrọ̀* kò ní ṣeni láǹfààní ní ọjọ́ ìbínú ńlá,+Àmọ́ òdodo ló ń gbani lọ́wọ́ ikú.+ Mátíù 6:25 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 25 “Torí náà, mo sọ fún yín pé: Ẹ yéé ṣàníyàn+ nípa ẹ̀mí* yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.+ Ṣé ẹ̀mí* ò ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ ni, tí ara sì ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ?+ 1 Tímótì 6:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Torí náà, tí a bá ti ní oúnjẹ* àti aṣọ,* àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.+
25 “Torí náà, mo sọ fún yín pé: Ẹ yéé ṣàníyàn+ nípa ẹ̀mí* yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.+ Ṣé ẹ̀mí* ò ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ ni, tí ara sì ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ?+