-
Lúùkù 9:46-48Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
46 Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù nínú wọn.+ 47 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn, ó wá mú ọmọ kékeré kan, ó mú un dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, 48 ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá gba ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi gba èmi náà; ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.+ Torí ẹni tó bá hùwà bí ẹni tó kéré láàárín gbogbo yín ni ẹni tó tóbi.”+
-