43 Jósẹ́fù ará Arimatíà wá, ọ̀kan lára àwọn Ìgbìmọ̀ ni, ẹni tí wọ́n kà sí èèyàn dáadáa, tí òun náà ń retí Ìjọba Ọlọ́run. Ó fi ìgboyà wọlé lọ síwájú Pílátù, ó sì ní kó gbé òkú Jésù fún òun.+
25 Wò ó! ọkùnrin kan wà ní Jerúsálẹ́mù tó ń jẹ́ Síméónì, olódodo àti ẹni tó ní ìfọkànsìn ni ọkùnrin yìí, ó ń dúró de ìgbà tí a máa tu Ísírẹ́lì nínú,+ ẹ̀mí mímọ́ sì wà lára rẹ̀.