18 Jékọ́bù rìnrìn àjò wá láti Padani-árámù,+ ó sì dé sí ìlú Ṣékémù+ ní ilẹ̀ Kénáánì+ ní àlàáfíà, ó wá pàgọ́ sí tòsí ìlú náà. 19 Ó ra apá kan lára ilẹ̀ tó pa àgọ́ rẹ̀ sí lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì, bàbá Ṣékémù, ó rà á ní ọgọ́rùn-ún (100) ẹyọ owó.+
32 Wọ́n sin àwọn egungun Jósẹ́fù,+ èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó kúrò ní Íjíbítì sí Ṣékémù lórí ilẹ̀ tí Jékọ́bù fi ọgọ́rùn-ún (100) ẹyọ owó+ rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì,+ bàbá Ṣékémù; ó sì di ogún àwọn ọmọ Jósẹ́fù.+