Mátíù 3:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Wò ó! Ohùn kan tún dún láti ọ̀run+ pé: “Èyí ni Ọmọ mi,+ àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.”+ Jòhánù 3:35 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 35 Baba nífẹ̀ẹ́ Ọmọ,+ ó sì ti fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.+ Jòhánù 10:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Ìdí nìyí tí Baba fi nífẹ̀ẹ́ mi,+ torí pé mo fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀,+ kí n lè tún rí i gbà. 2 Pétérù 1:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Torí ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba, nígbà tí ògo ọlá ńlá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún un* pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́ mi, ẹni tí èmi fúnra mi tẹ́wọ́ gbà.”+
17 Torí ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba, nígbà tí ògo ọlá ńlá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún un* pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́ mi, ẹni tí èmi fúnra mi tẹ́wọ́ gbà.”+