ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 14:14-17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Nígbà tó wá sí etíkun, ó rí èrò rẹpẹtẹ, àánú wọn ṣe é,+ ó sì wo àwọn tó ń ṣàìsàn nínú wọn sàn.+ 15 Àmọ́ nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ibí yìí dá, ọjọ́ sì ti lọ; jẹ́ kí àwọn èèyàn yìí máa lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé, kí wọ́n sì ra ohun tí wọ́n máa jẹ.”+ 16 Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wọn ò nílò kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.” 17 Wọ́n sọ fún un pé: “A ò ní nǹkan kan níbí àfi búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì.”

  • Máàkù 6:35-38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 35 Ọjọ́ ti ń lọ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ibí yìí dá, ọjọ́ sì ti lọ.+ 36 Ní kí wọ́n máa lọ, kí wọ́n lè lọ sí ìgbèríko àti àwọn abúlé tó wà ní àyíká, kí wọ́n sì ra ohun tí wọ́n máa jẹ.”+ 37 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.” Ni wọ́n bá fèsì pé: “Ṣé ká lọ ra búrẹ́dì igba (200) owó dínárì,* ká sì fún àwọn èèyàn yìí jẹ?”+ 38 Ó sọ fún wọn pé: “Búrẹ́dì mélòó lẹ ní? Ẹ lọ wò ó!” Lẹ́yìn tí wọ́n wò ó, wọ́n sọ pé: “Márùn-ún, pẹ̀lú ẹja méjì.”+

  • Lúùkù 9:12, 13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ọjọ́ ti ń lọ. Àwọn méjìlá náà wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ní kí àwọn èrò náà máa lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé àti ìgbèríko tó wà ní àyíká, kí wọ́n lè ríbi dé sí, kí wọ́n sì lè rí oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ, torí ibi tó dá la wà yìí.”+ 13 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.”+ Wọ́n sọ pé: “A ò ní ju búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì, àfi bóyá tí àwa fúnra wa bá lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn èèyàn yìí.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́