Mátíù 12:38 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 38 Àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wá fún un lésì pé: “Olùkọ́, a fẹ́ rí àmì kan látọ̀dọ̀ rẹ.”+ Máàkù 8:12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 12 Torí náà, ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi nínú ẹ̀mí rẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ló dé tí ìran yìí ń wá àmì?+ Lóòótọ́ ni mo sọ, a ò ní fún ìran yìí ní àmì kankan.”+ Jòhánù 2:18 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 18 Torí náà, àwọn Júù sọ fún un pé: “Àmì wo lo máa fi hàn wá,+ torí o ti ń ṣe àwọn nǹkan yìí?” 1 Kọ́ríńtì 1:22 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 22 Nítorí àwọn Júù ń béèrè àmì,+ àwọn Gíríìkì sì ń wá ọgbọ́n;
38 Àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wá fún un lésì pé: “Olùkọ́, a fẹ́ rí àmì kan látọ̀dọ̀ rẹ.”+
12 Torí náà, ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi nínú ẹ̀mí rẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ló dé tí ìran yìí ń wá àmì?+ Lóòótọ́ ni mo sọ, a ò ní fún ìran yìí ní àmì kankan.”+