22 Ohun tó mú kí àwọn òbí rẹ̀ sọ àwọn nǹkan yìí ni pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn Júù,+ torí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan tẹ́lẹ̀ pé, tí ẹnikẹ́ni bá gbà pé òun ni Kristi, wọ́n máa lé ẹni yẹn kúrò nínú sínágọ́gù.+
42 Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú àwọn alákòóso pàápàá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lóòótọ́,+ àmọ́ wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí àwọn Farisí, kí wọ́n má bàa lé wọn kúrò nínú sínágọ́gù;+
38 Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, Jósẹ́fù ará Arimatíà, tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àmọ́ tí kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí pé ó ń bẹ̀rù àwọn Júù,+ béèrè lọ́wọ́ Pílátù pé kó jẹ́ kí òun gbé òkú Jésù lọ, Pílátù sì gbà á láyè. Torí náà, ó wá gbé òkú rẹ̀ lọ.+