8 Àmọ́, ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín,+ ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí+ mi ní Jerúsálẹ́mù,+ ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà+ àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”*+
22 “Ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí: Jésù ará Násárẹ́tì ni ọkùnrin tí Ọlọ́run fi hàn yín ní gbangba nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ agbára àti àwọn ohun ìyanu* pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ rẹ̀ láàárín yín,+ bí ẹ̀yin fúnra yín ṣe mọ̀.