28 Torí náà, Jésù sọ pé: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti gbé Ọmọ èèyàn sókè,+ ìgbà yẹn lẹ máa wá mọ̀ pé èmi ni+ àti pé mi ò dá ṣe nǹkan kan lérò ara mi;+ àmọ́ bí Baba ṣe kọ́ mi gẹ́lẹ́ ni mò ń sọ àwọn nǹkan yìí.
10 Ṣé o ò gbà pé mo wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba àti pé Baba wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ni?+ Kì í ṣe èrò ara mi+ ni àwọn nǹkan tí mò ń sọ fún yín, àmọ́ Baba tó ṣì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀.