-
Mátíù 26:59-61Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
59 Àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sàhẹ́ndìrìn ń wá ẹ̀rí èké tí wọ́n máa fi mú Jésù kí wọ́n lè pa á.+ 60 Àmọ́ wọn ò rí ìkankan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹlẹ́rìí èké ló jáde wá.+ Nígbà tó yá, àwọn méjì wá síwájú, 61 wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó tẹ́ńpìlì Ọlọ́run palẹ̀, kí n sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ.’”+
-
-
Máàkù 14:57, 58Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
57 Bákan náà, àwọn kan ń dìde, wọ́n sì ń jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ń sọ pé: 58 “A gbọ́ tó sọ pé, ‘Màá wó tẹ́ńpìlì yìí tí wọ́n fi ọwọ́ kọ́ palẹ̀, màá sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ òmíràn tí wọn ò fi ọwọ́ kọ́.’”+
-