23 Tí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí yín ní ìlú kan, ẹ sá lọ sí òmíràn;+ torí lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé ẹ ò lè lọ yí ká àwọn ìlú Ísírẹ́lì tán títí Ọmọ èèyàn fi máa dé.
19 Nígbà náà, àwọn tí ìpọ́njú tó wáyé nítorí Sítéfánù mú kí wọ́n tú ká+ ń lọ títí dé Foníṣíà, Sápírọ́sì àti Áńtíókù, àmọ́ àwọn Júù nìkan ni wọ́n ń wàásù fún.+