2 Torí náà, bí àṣà Pọ́ọ̀lù,+ ó wọlé lọ bá wọn, ó sì bá wọn fèròwérò látinú Ìwé Mímọ́ fún sábáàtì mẹ́ta,+ 3 ó ń ṣàlàyé, ó sì ń tọ́ka sí àwọn ohun tó fi ẹ̀rí hàn pé ó pọn dandan kí Kristi jìyà,+ kí ó sì dìde kúrò nínú ikú,+ ó sọ pé: “Èyí ni Kristi náà, Jésù tí mò ń kéde fún yín.”