ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Lúùkù 4:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Jésù dá a lóhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+

  • Ìṣe 14:12-15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pe Bánábà ní Súúsì, wọ́n sì ń pe Pọ́ọ̀lù ní Hẹ́mísì, torí òun ló máa ń sọ̀rọ̀ jù. 13 Àlùfáà Súúsì tí tẹ́ńpìlì rẹ̀ wà ní àbáwọlé ìlú náà mú àwọn akọ màlúù àti òdòdó ẹ̀yẹ* wá sí ẹnubodè, òun àti ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà níbẹ̀ sì fẹ́ rúbọ.

      14 Àmọ́, nígbà tí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n jẹ́ àpọ́sítélì gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n bẹ́ sáàárín èrò náà, wọ́n sì ké jáde pé: 15 “Ẹ̀yin èèyàn, kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Èèyàn bíi tiyín ni wá, àwa náà ní àwọn àìlera tí ẹ ní.+ Ìhìn rere ni à ń kéde fún yín, kí ẹ lè yí pa dà kúrò nínú àwọn ohun asán yìí sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè, ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti òkun pẹ̀lú gbogbo ohun tó wà nínú wọn.+

  • Ìfihàn 19:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ni mo bá wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ láti jọ́sìn rẹ̀. Àmọ́ ó sọ fún mi pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀!+ Ẹrú bíi tìẹ ni mí àti ti àwọn arákùnrin rẹ tí iṣẹ́ wọn jẹ́ láti jẹ́rìí nípa Jésù.+ Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn!+ Torí ìjẹ́rìí nípa Jésù ló ń mí sí àsọtẹ́lẹ̀.”+

  • Ìfihàn 22:8, 9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Èmi Jòhánù fi ojú ara mi rí àwọn nǹkan yìí, mo sì fi etí ara mi gbọ́ ọ. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí i, mo wólẹ̀ láti jọ́sìn ní ẹsẹ̀ áńgẹ́lì tó ń fi àwọn nǹkan yìí hàn mí. 9 Àmọ́ ó sọ fún mi pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Ẹrú bíi tìẹ ni mí àti ti àwọn arákùnrin rẹ wòlíì àti àwọn tó ń pa àwọn ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé yìí mọ́. Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́