-
Ìfihàn 22:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Èmi Jòhánù fi ojú ara mi rí àwọn nǹkan yìí, mo sì fi etí ara mi gbọ́ ọ. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí i, mo wólẹ̀ láti jọ́sìn ní ẹsẹ̀ áńgẹ́lì tó ń fi àwọn nǹkan yìí hàn mí. 9 Àmọ́ ó sọ fún mi pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Ẹrú bíi tìẹ ni mí àti ti àwọn arákùnrin rẹ wòlíì àti àwọn tó ń pa àwọn ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé yìí mọ́. Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn.”+
-