28 Ọlọ́run ti yan ẹnì kọ̀ọ̀kan sínú ìjọ: èkíní, àwọn àpọ́sítélì;+ èkejì, àwọn wòlíì;+ ẹ̀kẹta, àwọn olùkọ́;+ lẹ́yìn náà, àwọn iṣẹ́ agbára;+ lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀bùn ìwòsàn;+ àwọn iṣẹ́ ìrànwọ́; àwọn agbára láti máa darí+ àti oríṣiríṣi èdè.*+
11 Ó fúnni ní àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bíi wòlíì,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere,*+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́,+12 láti tọ́ àwọn ẹni mímọ́ sọ́nà,* fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, láti gbé ara Kristi ró,+