6Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ní báyìí, wàá rí ohun tí màá ṣe sí Fáráò.+ Ọwọ́ agbára ló máa mú kó fi wọ́n sílẹ̀, ọwọ́ agbára ló sì máa mú kó lé wọn kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.”+
6 “Torí náà, sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Èmi ni Jèhófà, màá mú yín kúrò lábẹ́ àjàgà àwọn ará Íjíbítì, màá sì gbà yín sílẹ̀ lóko ẹrú.+ Màá fi apá mi tí mo nà jáde* àti àwọn ìdájọ́ tó rinlẹ̀ gbà yín pa dà.+
6 Torí èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà Ọlọ́run yín sì ti yàn yín kí ẹ lè di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,* nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.+
8 Àmọ́ torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, tó sì ṣe ohun tó búra fún àwọn baba ńlá yín+ pé òun máa ṣe ni Jèhófà ṣe fi ọwọ́ agbára mú yín kúrò, kó lè rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú,+ kúrò lọ́wọ́* Fáráò ọba Íjíbítì.