-
Léfítíkù 7:26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí+ ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé, ì báà jẹ́ ti ẹyẹ tàbí ti ẹranko.
-
-
1 Sámúẹ́lì 14:32, 33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Àwọn èèyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi wàdùwàdù kó ẹrù ogun, wọ́n mú àgùntàn àti màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n lórí ilẹ̀, wọ́n sì ń jẹ ẹran náà tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.+ 33 Torí náà, wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Wò ó! Àwọn èèyàn yìí ń dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà nítorí wọ́n ń jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.”+ Ni ó bá sọ pé: “Ẹ ti hùwà àìṣòótọ́. Ẹ yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ mi kíákíá.”
-