10 “‘Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì tàbí tí àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín bá jẹ ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí, ó dájú pé mi ò ní fi ojú rere wo ẹni* tó ń jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.
33 Torí náà, wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Wò ó! Àwọn èèyàn yìí ń dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà nítorí wọ́n ń jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.”+ Ni ó bá sọ pé: “Ẹ ti hùwà àìṣòótọ́. Ẹ yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ mi kíákíá.”
29 láti máa ta kété sí àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà,+ láti máa ta kété sí ẹ̀jẹ̀,+ sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa*+ àti sí ìṣekúṣe.*+ Tí ẹ bá ń yẹra fún àwọn nǹkan yìí délẹ̀délẹ̀, ẹ ó láásìkí. Kí ara yín ó le o!”*