ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìṣe 20:34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé àwọn ọwọ́ yìí ti pèsè àwọn ohun tí mo nílò+ àti àwọn ohun tí àwọn tó wà pẹ̀lú mi nílò.

  • 1 Kọ́ríńtì 4:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Títí di wákàtí yìí, ebi ń pa wá,+ òùngbẹ ń gbẹ wá,+ a ò rí aṣọ tó dáa wọ̀,* wọ́n ń nà wá,*+ a ò sì rí ilé gbé, 12 à ń ṣe làálàá, a sì ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́.+ Nígbà tí wọ́n ń bú wa, à ń súre;+ nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, à ń fara dà á pẹ̀lú sùúrù;+

  • 1 Kọ́ríńtì 9:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Àmọ́ mi ò tíì lo ìkankan nínú àwọn ìpèsè yìí.+ Ní tòótọ́, mi ò ṣe àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yìí torí kí a lè ṣe wọ́n fún mi, torí ó sàn kí n kú ju kí n jẹ́ kí ẹnì kan gba ẹ̀tọ́ tí mo ní láti ṣògo!+

  • 1 Tẹsalóníkà 2:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Ẹ̀yin ará, ó dájú pé ẹ rántí òpò* àti làálàá wa. A ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru ká má bàa di ẹrù wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn,+ nígbà tí a wàásù ìhìn rere Ọlọ́run fún yín.

  • 2 Tẹsalóníkà 3:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 bẹ́ẹ̀ la ò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́.*+ Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú òpò* àti làálàá, à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru kí a má bàa gbé ẹrù tó wúwo wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn.+

  • 2 Tẹsalóníkà 3:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Kódà, nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a máa ń pa àṣẹ yìí fún yín pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kó má jẹun.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́