-
Ìṣe 16:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí à ń lọ síbi àdúrà, ìránṣẹ́bìnrin kan tó ní ẹ̀mí kan, ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́,+ pàdé wa. Ó máa ń fi iṣẹ́ wíwò* mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀. 17 Ọmọbìnrin yìí ń tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti àwa náà, ó sì ń ké jáde pé: “Ẹrú Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ ni àwọn ọkùnrin yìí,+ wọ́n sì ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yín.”
-