-
Ìṣe 18:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Àmọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, Gálíò sọ fún àwọn Júù pé: “Ẹ̀yin Júù, tó bá jẹ́ lórí ìwà àìtọ́ tàbí ìwà ọ̀daràn ni, ó máa bọ́gbọ́n mu pé kí n fi sùúrù gbọ́ yín. 15 Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ àti àwọn orúkọ àti òfin yín ni,+ ẹ̀yin fúnra yín ni kí ẹ lọ bójú tó o. Mi ò fẹ́ ṣe ìdájọ́ lórí àwọn nǹkan yìí.”
-
-
Ìṣe 23:26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 “Kíláúdíù Lísíà sí Ọlọ́lá Jù Lọ, Gómìnà Fẹ́líìsì: Mo kí ọ!
-
-
Ìṣe 23:29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Mo rí i pé wọ́n fẹ̀sùn kàn án lórí àwọn ọ̀ràn Òfin wọn,+ àmọ́ kò ṣe ohunkóhun tó yẹ fún ikú tàbí fún ìdè.
-