6 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí i pé apá kan wọn jẹ́ Sadusí, àwọn tó kù sì jẹ́ Farisí, ó ké jáde ní Sàhẹ́ndìrìn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, Farisí ni mí,+ mo sì jẹ́ ọmọ àwọn Farisí. Torí ìrètí àjíǹde àwọn òkú ni wọ́n ṣe ń dá mi lẹ́jọ́.”
19 Ẹ máa gbàdúrà fún èmi náà, kí a lè fún mi lọ́rọ̀ sọ tí mo bá la ẹnu mi, kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà tí mo bá ń sọ àṣírí mímọ́ ìhìn rere,+20 èyí tí mo torí rẹ̀ jẹ́ ikọ̀+ tí a fi ẹ̀wọ̀n dè, kí n lè máa fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bó ṣe yẹ.