2 Àwọn èèyàn máa lé yín kúrò nínú sínágọ́gù.+ Kódà, wákàtí náà ń bọ̀, nígbà tí ẹnikẹ́ni tó bá pa yín+ máa rò pé ṣe lòun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run. 3 Àmọ́ wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan yìí torí pé wọn ò tíì wá mọ Baba, wọn ò sì tíì wá mọ̀ mí.+
13 bó tiẹ̀ jẹ́ pé asọ̀rọ̀ òdì ni mí tẹ́lẹ̀, mo máa ń ṣe inúnibíni, mo sì jẹ́ aláfojúdi.+ Síbẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, torí àìmọ̀kan ni mo fi hùwà, mi ò sì ní ìgbàgbọ́.