11 Ìgbàgbọ́ mú kí Sérà náà gba agbára láti lóyún ọmọ, kódà nígbà tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti kọjá ti ẹni tó lè bímọ,+ torí ó ka Ẹni tó ṣe ìlérí náà sí olóòótọ́. 12 Torí èyí, nípasẹ̀ ọkùnrin kan tó ti ń kú lọ,+ a bí àwọn ọmọ + tó pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí wọn ò sì ṣeé kà bí iyanrìn etí òkun.+