-
Fílípì 1:18-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Kí ló ti wá yọrí sí? Ní gbogbo ọ̀nà, ì báà jẹ́ nínú dídíbọ́n tàbí ní òótọ́, à ń kéde Kristi, èyí sì ń múnú mi dùn. Kódà, ṣe ni inú mi á túbọ̀ máa dùn, 19 torí mo mọ̀ pé èyí máa yọrí sí ìgbàlà mi nípasẹ̀ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ yín+ àti ìtìlẹyìn ẹ̀mí Jésù Kristi.+ 20 Èyí bá ohun tí mò ń fojú sọ́nà fún, tí mo sì ń retí mu, pé ojú ò ní tì mí lọ́nàkọnà, àmọ́ pé nínú bí mo ṣe lómìnira láti sọ̀rọ̀ fàlàlà, a ó ti ara mi gbé Kristi ga báyìí, bí a ṣe ń gbé e ga tẹ́lẹ̀, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ ìyè tàbí nípasẹ̀ ikú.+
-