8 Tóò, mo sọ fún àwọn tí kò gbéyàwó àti àwọn opó pé ó sàn kí wọ́n wà bí mo ṣe wà.+9 Àmọ́ tí wọn ò bá lè mára dúró, kí wọ́n gbéyàwó, torí ó sàn láti gbéyàwó ju kí ara ẹni máa gbóná nítorí ìfẹ́ ìbálòpọ̀.+
14 Torí náà, ó wù mí kí àwọn opó tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré ní ọkọ,+ kí wọ́n bímọ,+ kí wọ́n máa tọ́jú ilé, kí wọ́n má bàa fàyè gba àwọn alátakò láti fẹ̀sùn kàn wọ́n.