22 Ìwọ Ísírẹ́lì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn rẹ
Pọ̀ bí iyanrìn òkun,
Àṣẹ́kù wọn nìkan ló máa pa dà.+
A ti pinnu ìparun ráúráú,+
Ìdájọ́ òdodo sì máa bò wọ́n.+
23 Àní, ìparun ráúráú tí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun pinnu,
Máa ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ náà.+