-
Éfésù 2:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Ó lo ẹran ara rẹ̀ láti fòpin sí ọ̀tá náà, ìyẹn, Òfin tí àwọn àṣẹ àti ìlànà wà nínú rẹ̀, kí ó lè mú kí àwùjọ méjèèjì ṣọ̀kan pẹ̀lú ara rẹ̀, kí wọ́n lè di ẹni tuntun kan,+ kí ó sì mú àlàáfíà wá
-
-
Kólósè 2:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Yàtọ̀ síyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àwọn àṣemáṣe yín àti nínú ipò àìdádọ̀dọ́* ẹran ara yín, Ọlọ́run mú kí ẹ wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.+ Ó dárí gbogbo àṣemáṣe wa jì wá tinútinú,+ 14 ó pa ìwé àfọwọ́kọ rẹ́,*+ èyí tí àwọn àṣẹ wà nínú rẹ̀,+ tó sì lòdì sí wa.+ Ó mú un kúrò lọ́nà bí ó ṣe kàn án mọ́ òpó igi oró.*+
-