23 Nígbà tí wọ́n sọ̀rọ̀ àbùkù sí i,*+ kò sọ̀rọ̀ àbùkù sí wọn* pa dà.+ Nígbà tó ń jìyà,+ kò bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀, àmọ́ ó fi ara rẹ̀ sí ìkáwọ́ Ẹni tó ń dájọ́+ òdodo.
9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú,+ ẹ má sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù san ọ̀rọ̀ àbùkù.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre,+ torí ọ̀nà yìí la pè yín sí, kí ẹ lè jogún ìbùkún.