-
2 Kọ́ríńtì 8:1-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fún àwọn ìjọ tó wà ní Makedóníà.+ 2 Nígbà tí àdánwò ńlá pọ́n wọn lójú, ayọ̀ tó gba ọkàn wọn bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ òtòṣì paraku fi hàn pé wọ́n ní ọrọ̀ nípa tẹ̀mí, torí pé wọ́n lawọ́ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.* 3 Bí agbára wọn ṣe gbé e tó ni,+ bẹ́ẹ̀ ni, mo jẹ́rìí sí i, kódà ó kọjá agbára wọn,+ 4 ṣe ni wọ́n lo ìdánúṣe, tí wọ́n ń bẹ̀ wá taratara pé kí a fún wọn láǹfààní láti ṣe ọrẹ, kí wọ́n lè ní ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìrànwọ́ fún àwọn ẹni mímọ́.+
-
-
2 Kọ́ríńtì 9:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 torí mo mọ bó ṣe ń yá yín lára, mo sì fi ń yangàn lójú àwọn ará Makedóníà, pé ó ti pé ọdún kan báyìí tí Ákáyà ti múra tán, ìtara yín sì ti mú kí èyí tó pọ̀ jù nínú wọn gbára dì.
-