-
Mátíù 18:15-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Bákan náà, tí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, lọ sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un* láàárín ìwọ àti òun nìkan.+ Tó bá fetí sí ọ, o ti jèrè arákùnrin rẹ.+ 16 Àmọ́ tí kò bá fetí sí ọ, mú ẹnì kan tàbí méjì dání, kó lè jẹ́ pé nípa ẹ̀rí* ẹni méjì tàbí mẹ́ta, a ó fìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀.+ 17 Tí kò bá fetí sí wọn, sọ fún ìjọ. Tí kò bá fetí sí ìjọ pàápàá, bí èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè+ àti agbowó orí+ ni kó rí sí ọ gẹ́lẹ́.
-