20 Ó dájú pé, lẹ́yìn tí ìmọ̀ tó péye nípa Jésù Kristi Olúwa àti Olùgbàlà bá ti mú kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbin ayé,+ tí wọ́n bá tún pa dà sí àwọn nǹkan yìí tó sì borí wọn, ìgbẹ̀yìn wọn ti burú ju ìbẹ̀rẹ̀ wọn.+
7 Ọ̀rọ̀ yẹn kan náà la fi tọ́jú àwọn ọ̀run àti ayé tó wà báyìí pa mọ́ de iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+