-
1 Jòhánù 4:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Báyìí lẹ ṣe máa mọ̀ bóyá ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ kan tó ní ìmísí ti wá: Gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí tó bá fi hàn pé Jésù Kristi wá nínú ẹran ara jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ 3 Àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí tí kò bá fi hàn pé Jésù wá, kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ Bákan náà, ọ̀rọ̀ yìí ni aṣòdì sí Kristi mí sí, ẹni tí ẹ gbọ́ pé ó ń bọ̀,+ ó sì ti wà ní ayé báyìí.+
-