-
Ìṣe 3:5-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ló bá ń wò wọ́n, ó sì ń retí pé òun máa rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn. 6 Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Mi ò ní fàdákà àti wúrà, àmọ́ ohun tí mo ní ni màá fún ọ. Ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárẹ́tì, máa rìn!”+ 7 Ló bá di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, ó sì gbé e dìde.+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ àti ọrùn ẹsẹ̀ rẹ̀ le gírígírí;+ 8 ó fò sókè,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, ó tẹ̀ lé wọn wọ tẹ́ńpìlì, ó ń rìn, ó ń fò sókè, ó sì ń yin Ọlọ́run.
-