14 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Èrè Íjíbítì àti ọjà Etiópíà àtàwọn Sábéà, àwọn tó ga,
Máa wá bá ọ, wọ́n á sì di tìrẹ.
Wọ́n á máa rìn lẹ́yìn rẹ, pẹ̀lú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè wọ́n,
Wọ́n á wá bá ọ, wọ́n á sì tẹrí ba fún ọ.+
Wọ́n á gbàdúrà, wọ́n á sọ fún ọ pé, ‘Ó dájú pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ,+
Kò sì sí ẹlòmíì; kò sí Ọlọ́run míì.’”