13 títí gbogbo wa á fi ṣọ̀kan* nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé* ọkùnrin,+ tí a ó sì dàgbà dé ìwọ̀n kíkún ti Kristi.
14 Àmọ́ àwọn tó dàgbà ni oúnjẹ líle wà fún, àwọn tó ti kọ́ agbára ìfòyemọ̀* wọn nípa bí wọ́n ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.