-
Hébérù 5:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Torí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ẹ ti di olùkọ́ báyìí,* ẹ ṣì tún nílò kí ẹnì kan máa kọ́ yín láti ìbẹ̀rẹ̀ nípa àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀+ tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ ti Ọlọ́run, ẹ sì ti pa dà di ẹni tó nílò wàrà, kì í ṣe oúnjẹ líle. 13 Torí gbogbo ẹni tí kò yéé mu wàrà kò mọ ọ̀rọ̀ òdodo, torí pé ọmọdé ni.+ 14 Àmọ́ àwọn tó dàgbà ni oúnjẹ líle wà fún, àwọn tó ti kọ́ agbára ìfòyemọ̀* wọn nípa bí wọ́n ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.
-