5 Kì í ṣe pé àwa fúnra wa kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ohunkóhun, Ọlọ́run ló ń mú ká kúnjú ìwọ̀n,+ 6 ẹni tó mú ká kúnjú ìwọ̀n lóòótọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun kan,+ kì í ṣe ti àkọsílẹ̀ òfin,+ àmọ́ ó jẹ́ ti ẹ̀mí; torí àkọsílẹ̀ òfin ń dáni lẹ́bi ikú,+ àmọ́ ẹ̀mí ń sọni di ààyè.+