-
Ìṣe 18:26-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fìgboyà sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù, nígbà tí Pírísílà àti Ákúílà+ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un wọ àwùjọ wọn, wọ́n sì ṣàlàyé ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tó túbọ̀ péye. 27 Bákan náà, torí pé ó fẹ́ kọjá sí Ákáyà, àwọn ará kọ̀wé sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Torí náà, nígbà tó débẹ̀, ó ṣèrànwọ́ púpọ̀ fún àwọn tó ti di onígbàgbọ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run; 28 ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba pẹ̀lú ìtara, bó ṣe ń fi ẹ̀rí hàn kedere pé àwọn Júù kò tọ̀nà, tó sì ń fi hàn nínú Ìwé Mímọ́ pé Jésù ni Kristi náà.+
-