16 Kí ló pa òrìṣà pọ̀ mọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run?+ Nítorí àwa jẹ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run alààyè;+ bí Ọlọ́run ṣe sọ pé: “Èmi yóò máa gbé láàárín wọn,+ èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì di èèyàn mi.”+
5 bí àwọn òkúta ààyè, à ń fi ẹ̀yin pẹ̀lú kọ́ ilé tẹ̀mí+ kí ẹ lè di ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́, kí ẹ lè máa rú àwọn ẹbọ ẹ̀mí+ tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ Jésù Kristi.+