-
Róòmù 15:30-32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Ní báyìí, mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ìfẹ́ tí ẹ̀mí mú kí ẹ ní, pé kí a jọ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà sí Ọlọ́run nítorí mi,+ 31 kí a lè gbà mí+ lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Jùdíà, kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi lórí Jerúsálẹ́mù sì lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún àwọn ẹni mímọ́,+ 32 kó lè jẹ́ pé nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, màá wá sọ́dọ̀ yín tayọ̀tayọ̀, ara á sì tù mí pẹ̀lú yín.
-