11 Ẹ̀yin náà lè máa fi ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ yín ràn wá lọ́wọ́,+ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lè máa dúpẹ́ nítorí wa pé a rí inú rere gbà, èyí tó jẹ́ ìdáhùn àdúrà ọ̀pọ̀ èèyàn.*+
18 pẹ̀lú onírúurú àdúrà + àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, ẹ máa gbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.+ Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ wà lójúfò, kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo nítorí gbogbo àwọn ẹni mímọ́.
3 Lẹ́sẹ̀ kan náà, ẹ máa gbàdúrà fún wa+ pé kí Ọlọ́run ṣí ilẹ̀kùn fún ọ̀rọ̀ náà, kí a lè kéde àṣírí mímọ́ nípa Kristi, tí mo tìtorí rẹ̀ wà nínú ìdè ẹ̀wọ̀n,+