19 Ẹ máa gbàdúrà fún èmi náà, kí a lè fún mi lọ́rọ̀ sọ tí mo bá la ẹnu mi, kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà tí mo bá ń sọ àṣírí mímọ́ ìhìn rere,+20 èyí tí mo torí rẹ̀ jẹ́ ikọ̀+ tí a fi ẹ̀wọ̀n dè, kí n lè máa fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bó ṣe yẹ.
7 Ó tọ́ tí mo bá ronú lọ́nà yìí nípa gbogbo yín, torí ọ̀rọ̀ yín ń jẹ mí lọ́kàn, ẹ sì jẹ́ alájọpín pẹ̀lú mi nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi+ àti nínú bí a ṣe ń gbèjà ìhìn rere, tí a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.+