3 Ohun tí Òfin kò lè ṣe+ torí pé ẹran ara kò jẹ́ kó lágbára+ ni Ọlọ́run ṣe bó ṣe rán Ọmọ rẹ̀+ jáde bí èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀,+ kó lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dá ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi,
18 Torí náà, a pa àṣẹ ti tẹ́lẹ̀ tì torí pé kò lágbára, kò sì gbéṣẹ́ mọ́.+19 Torí Òfin ò sọ ohunkóhun di pípé,+ àmọ́ ìrètí tó dáa jù+ tó wọlé wá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tí à ń tipasẹ̀ rẹ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.+