-
Ìṣe 22:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Mo ṣe inúnibíni sí àwọn tó ń tẹ̀ lé Ọ̀nà yìí tí wọ́n fi kú, bí mo ṣe ń de tọkùnrin tobìnrin tí mo sì ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n,+
-
-
Ìṣe 26:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ní tèmi, mo gbà tẹ́lẹ̀ pé ó yẹ kí n gbé ọ̀pọ̀ àtakò dìde sí orúkọ Jésù ará Násárẹ́tì. 10 Ohun tí mo sì ṣe gẹ́lẹ́ ní Jerúsálẹ́mù nìyẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni mímọ́ ni mo tì mọ́ inú ẹ̀wọ̀n,+ torí mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà;+ nígbà tí wọ́n sì fẹ́ pa wọ́n, mo dìbò pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. 11 Bí mo ṣe ń fìyà jẹ wọ́n léraléra ní gbogbo sínágọ́gù, mo fipá mú wọn láti fi ìgbàgbọ́ wọn sílẹ̀; torí pé inú wọn ń bí mi gidigidi, mo bá a débi pé mo ṣe inúnibíni sí wọn ní àwọn ìlú tó wà lẹ́yìn òde pàápàá.
-