2 Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí* máa darí yín, àmọ́ ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà,+ kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí+ ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.
17 Nítorí náà, ohun tí màá sọ, tí màá sì jẹ́rìí sí nínú Olúwa ni pé kí ẹ má ṣe rìn mọ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń rìn,+ torí inú èrò asán* ni wọ́n ti ń rìn.+