22 Àwọn èrò tó wà níbẹ̀ dìde sí wọn lẹ́ẹ̀kan náà, lẹ́yìn tí àwọn adájọ́ kéékèèké sì ti ya aṣọ kúrò lára wọn, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n fi ọ̀pá nà wọ́n.+ 23 Lẹ́yìn tí wọ́n ti lù wọ́n nílùkulù, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì pa àṣẹ pé kí ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n máa ṣọ́ wọn lójú méjèèjì.+