-
Ìṣe 2:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “Ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí: Jésù ará Násárẹ́tì ni ọkùnrin tí Ọlọ́run fi hàn yín ní gbangba nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ agbára àti àwọn ohun ìyanu* pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ rẹ̀ láàárín yín,+ bí ẹ̀yin fúnra yín ṣe mọ̀. 23 Ọkùnrin yìí, tí a fà lé yín lọ́wọ́ nípasẹ̀ ìpinnu* àti ìmọ̀ Ọlọ́run,+ ni ẹ ti ọwọ́ àwọn arúfin kàn mọ́gi,* tí ẹ sì pa.+
-